PEN YORÙBÁ: ÌWÀ ÌBÀJÉ NÍ ORÍLÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ ÀTI NÍ ÀGBAYÉ


Láti Ọwọ́ Oyekanmi Abdulwarith Ayomide

Nàìjíríà jẹ́ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀, ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigeria ni èdè Gẹ̀ẹ́sì) jẹ́ orílẹ̀-èdè ìjọba àpapọ̀ olómìnira tí ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì ,tó fi mọ́ Agbẹ̀gbẹ̀ Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà ní apá Iwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Áfríkà. Orílẹ̀-èdè yí pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Benin ní apá ìwọ̀ Oòrùn, ó tún pààlà pẹ́lú orílẹ̀-èdè olómìnira ti Nijẹr ní apá àríwá, Chad àti Kamẹróòn ní apá ìlà Oòrùn àti Òkun Atlantiki ni apá gúúsù. Abuja ni ó jẹ́ Olú-Ìlú fún orílẹ̀-èdè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nàìjíríà ní ẹ̀yà púpọ̀, àwọn ẹ̀yà mẹ́ta ni wọ́n hànde tí wọ́n tóbi jùlọ, tí wọ́n sì pọ̀ jùlo, tí a sì kó àwọn ẹ̀ka ìsọ̀rí ìsọ̀rí èyà tókù sí abẹ́ wọn. Àwọn wọ̀nyí ni Ẹ̀ya Hausa, Ẹ̀ya Ìgbò ati Yorùbá.
Sùgbón Nàíjíríà jé ìlú tó kún fún waara àti oyin tí àwon adarí wa fún dànù bi omi ,Ìwà ìbàjẹ́ nínú ìjọba ni kí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ máa lo agbára tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ láti máa fi wá èrè sí àpò ara rẹ̀. Àmọ́, ìwà ìbàjẹ́ ju kéèyàn máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tún kan bí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì ṣe máa ń jí ẹrù ìjọba kó, tí wọ́n máa ń fi ipò wọn gba òun tí kò tọ́ sí wọn tàbí kí wọ́n kówó tó jẹ́ ti gbogbo aráàlú jẹ. Wọ́n tún máa ń lo agbára wọn láti fi àwọn èèyàn wọn sípò ńlá.
Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi tí ìwà ìbàjẹ́ ò sí, àmọ́ ó dà bíi pé ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Àwon eeso ise owo ìlù kumokumo naa ni àwon iwadi won to fi esè múlè lóríí awon òsìsé ìjoba ti won se owó ìlú lófò.
Ìwé 2013 Global Corruption Barometer tí àjọ Transparency International tẹ̀ jáde sọ pé, ibi márùn-ún tí àwọn èèyàn gbà pé ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ sí jù ni àárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn ọlọ́pàá, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn aṣòfin àti ní ilé ẹjọ́. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú àwọn ìròyìn tó ṣàlàyé ìṣòro yìí.
ÁFÍRÍKÀ: Lọ́dún 2013, wọ́n fẹ̀sùn kan nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] òṣìṣẹ́ ìjọba ní orílẹ̀-èdè South Africa nítorí ìwà jẹgúdújẹrá.
GÚÚSÙ AMẸ́RÍKÀ: Lọ́dún 2012, lórílẹ̀-èdè Brazil, èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ló jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n fi owó ìlú ra ìbò. Lára àwọn wọ̀nyí ni ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀gá àgbà òṣìṣẹ́ ìjọba, òun sì lẹni tó ṣìkejì lẹ́yìn ààrẹ ìlú.
ÉṢÍÀ: Nílùú Seoul lórílẹ̀-èdè South Korea, èèyàn méjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [502] ló kú nígbà tí ilé ìtajà kan wó lọ́dún 1995. Ìwádìí fi hàn pé àwọn kọngílá tó gba iṣẹ́ ìkọ́lé náà ti fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní ẹ̀gúnjẹ kí wọ́n lè lo ayédèrú kọnkéré kí ẹnikẹ́ni má sì yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò.
YÚRÓÒPÙ: Cecilia Malmström tó jẹ́ Kọmíṣọ́nnà tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ abẹ́lé fún Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé: “Ibi tí ọ̀rọ̀ ìwà ìbàjẹ́ nílẹ̀ wa dé lónìí kọjá sísọ, àwọn olóṣèlú ò sì ṣe tán láti wá nǹkan ṣe sí i.”
Ìwà ìbàjé jé ohun búburú láwùjọ, ejé ká sóra fún lópòlópò.

Post a Comment

0 Comments