Àbí OLÚBÀDÀN ti ìlu ÌBÀDÀN, Ọba Saliu Akanmu Adetunji (Ajé ògúngúnísò kinni) ni ojó kerìn din logbon osú kẹjọ, ọdún 1928 (26/8/1928), ó sì ku nì ojó keji osù kinni odun 2022 ti a wa yii (2/1/2022). Oloogbe je ọmọ odún meta le ni Aadorun (93). (Sun re ooo, ọba wa).
Erin ṣubú
Àjànàkú ṣubú, kò le dìde
OLÚBÀDÀN tí lọ!
Ikú pa abírí, abírí ku
Iku pa ábìrì, àbìrì rọ'run
Iku da oro nla si ilẹ̀ Ìbàdàn .
Baba mi Àkànmú ,
Igba Abẹ́rẹ́ kò tóo ko
Igba ìràwò kò tó ṣù
Okan soso òṣùpá
Oju igba fìtílà lọ
Adétúnjí ọmọ Balógun
Ebin pejo, awun nyan
Atawun atejo, ẹran jíjẹ
Atekirii ataja ẹran ìkòkò ni
Sún re oo!
Ibadan mesi ọ̀gọ̀, nílé Oluyole
Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun
Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya
Ilu Ajayi, o gbori Ẹ̀fọ̀n se fila-fila
Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo
Ibadan Omo ajoro sun,
Omo a je Igbin yoo, fi ikarahun fo ri mu
Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni,
Èyí too ja aladuugbo gbogbo logun,
Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun
Ibadan Kure!
Ibadan beere ki o too wọ o,
Ni bi olè gbe n jare olohun
B’Ibadan ti n gba onile bẹẹ lo n gba Ajoji;
Eleyẹle lomi ti teru-tọmo ‘Layipo n mu,
Asejire lomi abumu-buwe nilẹ Ibadan
A ki waye ka maa larun kan lara,
Ija igboro larun Ìbàdànn.
0 Comments